February 26, 2025

Èdè Ọkin Ọlọfamọjọ,
Ọmọ a jẹ anàmọ́ sú sì ẹyin ẹsẹ bẹtẹbẹtẹ
Ẹni tí ó ní jẹ ìyàn anàmọ́, olúwa rẹ kò ní de Ọ̀ffà ni
Ọmọ Onmọka
Ìjà àtàǹa lẹ gbé gbóná,
Mo sì gbé ìjà ru gẹngẹ bí ọsẹ
Ogbón-na Ìjàkadì oo
Ẹ̀yán tí ń bá bá já tí ń bá da
A jẹ wípé Ọlọfa kọ lọ bí mi
At’ọkùnrin Ọ̀ffà at’obìnrin Ọ̀ffà
Èyí tí ó bá lè já lo yà ọlẹ nílé wa
Wọn ò má gbọ́dọ̀ wá ọ níjà l’Ọ̀ffà
B’èèyàn ba wa ọ níjà, ọ ọ́ dá
Kò í rẹmi, ẹ máa tí là mi
Ti èèyàn bá là mi, yóò di t’olúwa rẹ
Ìjàkadì ó gbọ́dọ̀ hùn ọmọ Ọ̀ffà
Ọ̀ffà ń fà Ọlọfa ẹgbẹ́ rẹ lẹsẹ,
A to-n-torí ọmọ ọlọmọ
Mo s’Ọ̀ffà s’Ọ̀ffà, ìgbà tí ó tó, mo bá wọn tún ṣe Ido-Ọsun létí Ẹdẹ
Nílé Ọlalọmi, níbi tí òmì tí wọn tó ju ọtí lọ
O n kí mi, òun là mi
Ọlalọmi, àá tí ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń ṣeni tíì tún gbàní
Iyẹru, abẹ aka ó gbà ọmọ ẹṣin
Baluwẹ ó gbọmọ Imọdo
Èmi Ọ̀ffà
Ìwọ Ọ̀ffà
Ọ̀ffà máa fà mi
K’émi na ó fà ọ
Ẹ jẹ ká bọ síbi kọlọfin
Ká jọ man fà ìrun abẹ ara wa

*********************************************************

À-jùmọ̀-fà ni irun Ọ̀ffà.
Ọlalọmi ọmọ a bá ìṣù jookọ, Ìjàkadì lóró Ọ̀ffà
Ìjà pẹki abẹ òwúla.
Bi ko se ojú ebè l’Ọffa
A sójú pòrò lóko
Ibà sójú olóko iba láwọn
O sójú àgùnmọna l’Ọffa.
O sójú àgbélẹyarara.
O sójú aporubukako
Kínní ńṣe kangùn-kakanrun ni ilé Ọba?
Ọkà ni ńṣe kagun-kakanrun, Àgbàdo ni Àgùnmọna l’Ọ̀ffà
Eère ni Àgbélẹyarara, Iṣu ni aporubu ka oko
Ọmọ òdì mẹta ti nbẹ l’Ọ̀ffà
Òdì ti iwájú ni ti Olusanmi
Òdì àárín ni ti Olumọnrin
Òdì ti ẹyin ni ti Olugbensẹ Ọmọ Ayéjin
Ọmọ odò mẹta kan ti tún nbẹ l’Ọ̀ffà
Ìkan ni ka pa ehinla bọ òun ki òun di okùn
Ìkan ni ka pa àgbò bọ òun ki òun di ọsa
Ìkan ni ka pa àkùkọ ganga bọ òun ki òun di ọgbàgbà
Ọba ni ọ̀kọ̀ọ̀kan Ọ̀ffà ti t’àgbò ra, òdodo wọn ti to ehinla pa.
Ṣùgbọ́n bi ọkàn ba di okùn, ti ọkan ba d’ọsa
Níbo ni a ko ọmọ iyebíye wọ̀nyí si?
Èyí ti a pa ehinla fún o lè d’okùn
Èyí ti a pa àgbò fún o lè d’ọsa
Èyí ti a pa àkùkọ ganga fun, se oun lo di ọgbàgbà
O di Àgùnlóko l’Ọ̀ffà
O di òmí ti gbogbo Ọlalọmi nmu…
Pẹ́ki mo ba Ọdọ́fin di mù
Mose Ọjọ́mú kánrin kése,
Mofi ẹyin Ṣááwo ra’lẹ l’Ọ̀ffà
Ọ̀ffà o m’áka Àríjaṣòro,
Ọlalọmi lo lááre
Ọ̀ffà o m’áka, ègún ẹrú wọlẹ́ l’Ọ̀ffà ó jú ti ọmọ lọ
Ọmọ òkúta mẹta ńṣẹṣẹ ńṣẹṣẹ
Ìkan kọ mi lẹsẹ
Ìkan se’mi ni pẹ̀lẹ́
Ìkan se’mi rọra
Ìkan ni, nígbàtí mi ò m’ọ̀nà, kínní mo wa de ìlú èrò?
Ìkan ni, nígbàtí mi ò m’ọ̀nà, kínní mo wa de ìlú ète?
Ìkan ni, nígbàtí mi ò m’ọ̀nà kínní mo wa de ìlú ọ̀wọ́nwọn?
Nílé Ọlalọmi, níbi ti òmí ti wọn to ju ọtí lọ
Èdè Ọkin ti mo ri Ọkin bumú
Ti mo fi Ábátá sìn ẹsẹ̀ l’Ọ̀ffà
Ti mori Abelenjẹ bójú, ọmọ la k’Ọ̀ffà o kún kẹ́ẹ́kẹ́ẹ́
Ọlalọmi, ọmọ Órúbọ ńlá tíì ṣubú láró
Pápá ni ohùn bàtà,
O nki mi, O nlá mi;
Ọlalọmi, talo ṣeun nínú ara wọn?
Ilẹ́ yí ko gbaayé, a ko lo si Ọ̀ffà Maíkà
(This land [Ọ̀yọ́ Ilé] could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Maíkà)
Nígbàtí Ọ̀ffà Maíkà ko gba wa mọ, a ko lọ sí Ọ̀ffà Irese
(When Ọ̀ffà Maíkà could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Irese)
Nígbàtí Ọ̀ffà Irese ko gba wa mọ, a ko lọ sí Ọ̀ffà Ikose,
(When Ọ̀ffà Irese could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Ikose)
Nígbàtí Ọ̀ffà Ikose ko gba wa mọ, a ko lọ sí Ọ̀ffà Èésun,
(When Ọ̀ffà Ikose could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Èésun)
Nígbàtí Ọ̀ffà Èésun ko gba wa mọ, a ko lọ sí Ọ̀ffà Igbólotu
(When Ọ̀ffà Èésun could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Igbólotu)
Nígbàtí Ọ̀ffà Igbólotu ko gba wa mọ, a padà sí Ọ̀ffà Èésun,
(When Ọ̀ffà Igbólotu could not occupy us, we returned to Ọ̀ffà Èésun)
Nígbàtí Ọ̀ffà Èésun ko tún gba wa mọ, a ko lọ sí Igbo-Oro
(When Ọ̀ffà Èésun could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Igbó Oro)
Nígbàtí Igbo-Oro ko gba wa mọ, a ko lọ sí Ọ̀ffà Àrínlolu
(When Ọ̀ffà Igbó Oro could not occupy us, we moved to Ọ̀ffà Àrínlolu)

************************************************************
Ọlọfa se pẹ̀lẹ́ o
Akeekuya ni mọ’bi òkú ọpẹ
Amọ̀kòkò ni mọ’bi àmọ́ gbéepọ,
Iyẹru Ọkin, ọmọ àríja ṣòro
Akééru ni mọ’bi òkú ọpẹ
Amọkòkò ní í mọ’bi amọ̀ gbé pọ
Ojú tí dáró dáró Onímọ̀ká
O dáró tán, ọwọ́ ẹ dúdú
Aró dúdú, aró ò yá bù mu
Aró dúdú, aró ò yá bù wẹ̀
Èdè Olèle, arò ko ya bu bọ́jú
Ọmọ iṣu gbádági
Tí í yọ olóko lẹ́nu
Ìyẹ̀rú ọ̀kín Ọlọ́famọjọ́
Òtòṣì Ọ̀ffà ní í f’ọwọ́ l’àká ẹ jẹ́jẹ́
Olówó ibẹ̀ ní í f’ọwọ́ l’aro
Òrìṣà jẹ ń lá n’Ìyẹ̀rú
K’emi náà o m’ọwọ l’aro
Kí n m’ẹsẹ l’aro
Ọfà Ìmọ̀ká ọmọ Ayèéji
Igún ni mò ri ni mo dàṣà gbèrú
Àkàlà ni mo ri ni mo d’àṣà jẹdọ
Ọlọfa ni mo ri ni mo wa d’àṣà lami lábẹ́
Ọlalọmi ni mo ri ni mo d’àṣà lami lápá
O òsì rọra lami, tó o bá lami, májẹ ki ọbẹ̀ o jìnlẹblápá mi.
Ọkin Ọlọfa lónì Ọ̀ffà
Ọlọmọn lo ni ọmọn,
Gbengbeleku ni ara ìyókù ń ṣàn…..
Àlùkòso, Ọlọfa egbèje
Àlùbẹmbẹ, Ọlọfa ẹgbẹ́fa
Alukiri njigi, Ọlọfa ẹgbẹẹdogun.
Akẹ́bajẹ́ , lopa ọmọ Ọlọfamọjọ jẹ níjọ́ sì

************************************************************
Ọlọfamọjọ, ab’ìṣù joókọ̀
Ìjàkadì lóró Ọ̀ffà
Ìjà kàn, ìjà kán tí wọn ń jà l’Ọ̀̀ffà nílé Ọlalọmi
O sójú pòrò nínú oko
O sójú ebè láàlá
Kí bá sójú olóko kí bá làwọn
O di alakọkọ, mo gbọ́ pé wọn ò ja l’Ọ̀ffà nílé Ọlalọmi
Mo kò àpò, mo kò ada
Mo mú ọ̀tá wẹ́wẹ́
Mo dá sínú ìbọn
Mo gbé ẹyin bọ
Mo fi ṣe alakọkọ
Ọlalọmi ni kìí se ónìjà baba òun ni
O di ẹlẹ́keeji, mo gbọ́ pé wọn ò ja l’Ọ̀ffà nílé Ọlalọmi
Mo kò àpò, mo kò ada
Mo mú ọ̀tá wẹ́wẹ́
Mo dá sínú ìbọn
Mo gbé ẹyin bọ
Mo fi ṣe alakọkọ
Ọlalọmi ni kìí se ónìjà baba òun ni
O di ẹlẹ́ka ẹ́wẹ́, mo gbọ́ pé wọn ò ja l’Ọ̀ffà nílé Ọlalọmi
Mo kò àpò, mo kò ada
Mo mú ọ̀tá wẹ́wẹ́
Mo dá sínú ìbọn
Mo gbé ẹyin bọ
Mo fi ṣe alakọkọ
Ọlalọmi ni kìí se ónìjà baba òun ni
Mo ní, kínní ńṣe ónìjà baba rẹ gan?
Ò ní, òun ni ọ̀pápa-n-koko mo bá Ọdọfin dimu
Mo ṣe Ọjọ́mú kánrinkésè
Mo fi ẹyin Shawo ralẹ nìsàlẹ̀ Ọ̀ffà
**************************************************************
Ònímọka, báà bá má b’Ọlọfa lọ ojú ogún
Ọpẹpẹ̀ mo ríja ṣòro
Ọlọfamọjọ, ọmọ a-kàn-tí-aro, Ọ̀yẹ mo páráda mo d’épé nù
Ọmọ àgàn pápákọ-irínwó
Ọmọ apajúbà k’ẹgbẹ́fa
Ọmọ ọgbọ́-kúrùu k’ẹgbẹ́rìndínlógún
O torí baba wa Olúkúmọpa Àjànà mọ pá ni àgbon’do l’Àpàpà
Nígbàtí a gbọn’do l’Àpàpà nílé Olúṣàdé
Ọlọfamọjọ là pá ẹja ńláńlá bí apá, là pá ẹja ńláńlá bí ìtan bí ìtan
Ọkàn n tí abá Olúgbayìkẹ
Ń ó bá Ọlọfa lọ ojú ogun
Ọkàn ń tí Olúgẹlóye
Ọkàn ń tí ibà ibà mi, Ọ̀yọ́ soko, tí ń ore ń ní de láìlá
Ó torí Olúmọkọ Ọlọfamọjọ lọ́wọ́ ń tà ọmọ ará Ẹdẹ
Torí Olúmẹ̀mu ọwọ́ nt’ènìyàn ṣáṣá l’Ọ̀ffà
Ń dúró ní mo dúró, Ọlọfamọjọ, mo na ìgbà ẹni
Mo bẹ̀rẹ̀, mo na ìgbà ènìyàn
Ènìyàn mẹ́fà ló ṣẹ níja l’Ọ̀ffà
Àbíl’Ọ̀ffà, baba mi, mo dúró, mo na gbogbo wọn pátá pòrògódò
Mo na ènìyàn l’Ọ̀ffà
Ọmọ oguluntu balẹ̀, ó tà yẹgbẹ́ ká inú oko
Oko ìjà balẹ̀ tú yẹgbẹ́-yẹgbẹ́
Ìjà ó rẹmi, ẹ má tíì là mi nílé Olúṣàdé
Ẹni ó bá lami, yóò di t’olùwà rẹ
Ọpẹpẹ̀ mo ríja ṣòro
Ìjà ó pe mọ, mo gbé ìjà l’ọja
Nígbàtí ìjà ó pe mọ, mo gbé ìjà mi lọ inú Ìpara
Ọmọ àdàkudaru
Onmọka, ọmọ adádá bí irú dá-dá-dà
Níjọ́ ada ku,
Èlò l’a mú lọrèé gbìn ada nílé Olúṣàdé?
Aàrùn l’a mú lọrèé gbìn ada nílé Olúṣàdé
Èlé yí ni, oko àwo lo bá lọ
Yànmu yànmu jẹ lórí igba kòtò
Ọlọfamọjọ, baba Ọlalọmi, gùn ẹṣin bá orí afárá lọ
Afárá ṣubú, Ọ̀yẹku n de, àgànna Ọlọfa
Ń ó gbé ìjà lejù í-tẹ-ńgèlè
Onmọka, baba, mo gbé’jà ru gẹ́gẹ́rẹ bí Ọya
At’ọkùnrin at’obìnrin Ọ̀ffà
Nílé Onmọka óò,
Èyí tí ó bá lè já, lo ya ọlẹ nílé wa
Ìjà pẹkì abẹ owúlà, Ọmọ Ọlalọmi aríjaṣòro
Bí ó bá sójú ebè l’Ọ̀ffà asójú pòrò
Ọlọfa ọmọ làáre kò tóbi, kò dọ́gba;
Ọkàn kò gbọ́dọ̀ ju ọkàn
Ìyẹru, bí ọkàn ju ọkàn
Ọba níí kò wọn ní rorò
Ìyẹru òkun, ọmọ akin bí ẹni ń kí ọba
Ńkúrú l’a-i-kúrú
Bí bẹ̀rẹ̀ l’a bẹ̀rẹ̀ l’Ọ̀ffà
Ènìyàn ó ní gùngùn gùn kò bá wọn jo ìlù looro nílé Olúṣàdé
Níjọ́ baba mi Ìyẹru lòun ó di Ewulẹ l’Ọ̀ffà
Wọn ní kó tọju atààre
Ìyẹn ló d’ìbínú Ìyẹru Ọlọfamọjọ
O lòdì bí a bá pàdé ìjà lórí oko ẹ̀gàn nílé Òwú
Wọn pàdé ìjà lórí oko ẹ̀gàn ńìsàlẹ̀ ìsàlẹ̀
Àlùbẹ̀nbẹ̀ gorí Ìrókò
Ọlọfamọjọ àlùkòso ń gorí oro
O wa k’Afọn tí ó kó tó yọ ọ̀pá Ẹrifi lẹ́nu là-là-là
Ní ń pè T’kú fe
T’òye fe
Áà gbọ́dọ̀ fi àárọ̀ joyè kò m’ọ̀nà ọ̀tẹ̀
Tin bá ń lọ ilé àwọn baba mi, Ọpẹpẹ̀ mo ríja ṣòro
Ọ̀ffà nílé Onmọka, ọmọ Ọlalọmi o
Arìjàgba, gbéra nílẹ̀, ó dídé
Ogbóná Ìjàkadì
Mo kí ọ́ lọ́nà ìbẹ̀hun

********************************************************

Onmọka, ọmọ Ayéèjìn
Ọlalọmi Láàwore ọmọ obibọ
Àbójúagadabíiná
Ọ f’ẹsẹ ẹṣin méjèèjì
Ṣe ojú omi rúkúrúkú
Baba Ẹrùbàmì
Gbagùnlójú
Baba Asipa
O f’ọ̀tún jo Kòsọ
O f’òsì jo Gbẹdu
Fi ẹyin jo Abente
Baba àwọn Ìlu
Pọọla ntó kan
L’olórí wọn
Ẹni tí ó gbẹnu jo o jo ìlú ẹ̀dùn
Ab-èléko s’Ọsun
Ab’Akirun ṣe Irẹlẹ
Ahe ẹla ìlẹ́kẹ̀
Níjọ́ Oníre n bọ Ogun
Ọlalọmi
Owo mi ni
L’ahe níjọ́ Onira ń bọ̀ Ọya
Ọpapa lápá fi yà d’ààfin
Owíwí là wùyi lọgba Ọ̀ffà
Ìjà namọnamọ l’Ọ̀ffà
Ìjà namọnamọ ń’Ìyẹru
Akì í dá Baálẹ̀ ká sún ìlú
Lẹ dá Baálẹ̀ ká sún ìlú
Ẹ fi ẹyin Sáwọ ralẹ lọgba Ọ̀ffà
Ọ̀rọ̀ kan wà pá’ni pọ l’Ọ̀ffà
Wọn lọmọ olówó Ọ̀ffà
Wa lọ sí ẹ̀gàn
O rè wá ìṣù
Kò rí gbọọrọ
Ká má sún jẹ
Ọmọ òtòṣì Ọ̀ffà
Wa lọ sódó ó ré pọn omi
Kí ọmọ olówó rí òun mu
Ọmọ olówó Ọ̀ffà
O lọ sí ẹ̀gàn
O rè wá ìṣù
O rí gbọọrọ
O ni, amá sún jẹ
Ọmọ òtòṣì Ọ̀ffà
O ni òun ò ní lọ sódó ó ré pọn omi
Kí ọmọ olówó rí òun mu
A fọn kò dùn
A tẹ ẹ̀, kò yànu
Ọ̀rọ̀ di Ilé Àbiọdún Aláàfin Ọ̀yọ́
Atọbatẹ́lẹ̀, baba Ijadu
O lọmọ òtòṣì Ọ̀ffà
Kò má mú ọwọ́ là Àkà ẹ jẹjẹ
Ọlalọmi
Ọmọ bíbí ilé wa
Kò má mú ọwọ lu arò
Òrìṣà jẹ ń lá l’Ọ̀ffà
Ń m’ọwọ larò
Ń m’ẹsẹ larò
Gbogbo ọwọ tí mo ni
Ní mo fi larò
Abente kan pirimu
Àjòtawọtasẹ nílé Ọ̀ffà
Ìran baba Ọlọfa
Àwọn kìí l’èègun
Ọmọ kékeré Ọ̀ffà
Nii ṣeré ọ̀sẹ̀potu
Ní wọn dára wọn ní tètè
Obìnrin Ọlalọmi l’Ẹsa Ogbín ara Ogbojo
Mo mòun tó jẹ́ ègún ẹrúwọlé l’Ọ̀ffà
Ju ti ọmọ bíbí ilé wa lọ

***************************************************
Ọ̀ffà Mọka, ọmọ Ayéèjìn
Níjọ́ tí ègún ẹrú yíò wọlé ju t’ọ́mọ
Ọlalọmi, gbéra nílẹ
O dídé
Ọ̀fẹ́ lọ sí ojú ogun
Ọlalọmi wá fẹsẹ rẹ ilẹ̀
O wa fàya rẹ silẹ
Aya tí a wi yii lóyún sínú gẹrúgẹrú
O f’ẹrú rẹ silẹ
Loba lọ sójú ogun
Wàrà ooo
Wọn ní ẹrú Ọlalọmi
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin
K’ẹsin rí oún jẹ
Ẹrú Ọlalọmi kọ, ó lòun ó lè lọ
Wọn ní ìwọ ìwọfà Ọlalọmi
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin
K’ẹsin rí oún jẹ
Ìwọfà Ọlalọmi kọ, ó lòun ó lè lọ
Ọmọ bíbí Onmọka
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin
K’ẹsin rí oún jẹ
Ẹrú Ọlalọmi kọ, ó lòun ó lè lọ
Aya Ọlalọmi tó lóyún sínú gẹrúgẹrú
O gbéra nílẹ́
O bọ sì abẹ Àká
O lọ sì abẹ Àká
O lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin
K’ẹsin rí oún jẹ
Loba bímọ síbẹ̀
Wọn ni,
Ọmọ Ọlalọmi
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé kò ọmọ baba rẹ bọ síta/sóde
Torí ó bí ọmọ dá síbẹ̀
O ni, òun ó ní lọ rèé kò ọmọ baba òun bọ sóde
Wọn sì ń wí
Ìwọfà
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé kò ọmọ olúwa rẹ bọ síta/sóde
Torí ó bí ọmọ dá síbẹ̀
O ni, òun ó ní lọ rèé kò ọmọ olúwa òun bọ sóde
Wọn ní, ìwọ ẹrú Ọlọfa
Wá lọ abẹ Àká kò lọ rèé kò ọmọ olúwa rẹ bọ síta/sóde
Torí ó bí ọmọ dá síbẹ̀
O ni, lo bablọ rèé kò ọmọ olúwa rẹ bọ sóde
Nígbàtí Ọlalọmi dárí ogun de
Wọn làwọn pé ọmọ Ọmọ Ọlalọmi wá lọ abẹ Àká lọ rèé mú àgbàdo f’ẹsin
K’ẹsin rí oúnjẹ
O lòun ó lọ
Ọmọ wa lọ abẹ Àká,
Òun ó lọ
Ìwọfà, wá lọ abẹ Àká lọ rèé mú àgbàdo f’ẹsin
O ni òun ò lọ
Aya Ọlalọmi tó lóyún sínú gẹrúgẹrú
Òun ló lọ sì abẹ Àká
Òun ló lọ sì abẹ Àká
Òun ló lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin k’ori oún jẹ
Ibí tí ó lọ rèé mú àgbàdo f’ẹṣin k’ori oún jẹ
Loba bímọ dá síbẹ̀
Àwọn ni, Ọmọ Ọlalọmi
Wá lọ abẹ Àká
Kò lọ rèé kò ọmọ baba rẹ bọ síta
O kọ,
O lòun ó lọ
Àwọn ni Ìwọfà nílé Ọlọfa
Wá lọ abẹ Àká
Kò lọ rèé kò ọmọ baba rẹ bọ síta
O kọ,
O lòun ó lọ
Ẹrú Ọlọfa
Òun ló wà lọ abẹ Àká
Lo bá lọ réé k’ọmọ olówó rẹ bọ síta
Ọlalọmi (Ọba Olùgbénsẹ Ayéèjìn) ni, “to, to, to!
“Ọba boosa
“Oobe boore
” Anamu ni t’ọga
“Itọ tí a bá tú lẹ́nu kò gbọ́dọ̀ wọ ẹnu mọ”
O ni, ègún ẹrú wọlé ko máa wọlẹ l’Ọ̀ffà ju ti ọmọ lọ
Ọ̀ffà Onmọka, ọmọ Ayéèjìn
Ọlalọmi Lawoore
Ọmọ obibọ ńlá tíì ṣubú lu aró
Ọ̀yẹ somi rúkú lọ́nà t’Ọ̀ffà
Àwọn ọmọ òtòṣì Ọ̀ffà ni f’ọwọ l’aka ẹ jẹjẹ
Ọlalọmi, ọmọ bíbí ilé wa níí f’ọwọ laró
O n kì mi
O n là mi
O wa apala kan sàgada fi ṣá mi lẹhin ọrun
Tiwájú ni kí n kì ẹ fún ní, àbí t’ẹhin?
Pààpa lóhùn Bata
O n kì mi, òun là mi
Ọlalọmi, taloo ṣeun nínú ara wọn?
Ọlalọmi, áà ti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń s’eni tí tún ń gba’ni
Ọlalọmi, ọmọ obibọ ńlá tíì ṣubú lu aró
Ọmọ àkútan forí ẹgun s’ẹiyẹ
Ọmọ àikútan forí ẹgun s’ọ̀nà
Ọmọ kíkú orí ẹgun
Òun (àti) aṣọ funfun níí jọ lọ
Àjòjì kii bá wọn lọ ìdí ẹgun
Àjòjì tó bá bá wọn lọ ìdí ẹgun
Ẹdan nii wọn ń mú yọjú rẹ!
Béèrè lọ́dọ̀ Ajomúsánra kìkì ìlẹ́kẹ̀ l’ẹku l’Ọyẹ
Òun dùn “Pa”
Òun dùn “Pé”
O dàbí odo òde Iwéré
O dàbí odo òkè Ibéri
Ọwá rán kàkà l’ẹ fọn sẹgi dá sígbó
Ọlalọmi ni, “torí asẹwe, torí asẹgi”
Ọ̀ffà bẹ́ẹ̀ lẹ ni ọla tó, ọmọ Ayéèjìn
Bí wọn ba n sọpe ìjà pẹki abẹ òwú la
Ọlalọmi, ọmọ Sukuọ̀lalọ
Ogbó’nia (Ologboni) a sì pa ìtàn ara rẹ l’Ọ̀ffà
Níjọ kan
Ti ìjà ṣẹlẹ̀ l’Ọ̀ffà……..
Ìyẹ̀ru, ọmọ ọ̀wọ́nwọn
Nílé Ọlalọmi, níbi tí omi tí wọn tó ju ọtí lọ
Ìyẹ̀ru, arìjàsòro
Ìjà láwà fín ṣòro láàrin ilé wa
Tònmọka, ọmọ Ayéèjìn
Wọn bí mi nílé Ọlọfamọjọ
Ní wọn bá gbé mi sókè l’ẹmẹ́ta
Mo tún lè tepọn lórí ọpọn
Ọ̀ffà tònmọka, ọmọ Ayéèjìn

********************************************

Ìjà kàn, ìjà kán ti wọn n ja l’Ọ̀ffà
Lórí ọ̀kẹ́ mẹ́ta ló dá lé e
Wọn ní wọ́n ó pín owó
Wọ́n mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn mú ọ̀kẹ́ kan ẹwẹ
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọ́n sì tún mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Ṣàlàmọnlèkún tó sẹyin gúrúkan
Wọn tún ránju, wọn ń rán imú
Títí wọn jà l’Ọ̀ffà nílé Ọlalọmi
Wọn tún ní wón ó pín owó
Wọn tún pín owó
Wọ́n mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn mú ọ̀kẹ́ kan ẹwẹ
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọ́n sì tún mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Ṣàlàmọnlèkún tó sẹyin gúrúkan
Nínú ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́wàá tí wọn nja l’Ọ̀ffà nílé Ọlalọmi
Owó wá ku ọ̀kẹ́ mẹ́rin nílé wọn, Ọ̀ffà
Tònmọka, ọmọ Ayéèjìn
Wọn tún pín owó
Nílé Ọlọfamọjọ
Wọ́n mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọ́n sì tún mú ọ̀kẹ́ kan
Wọn fún Baba Ṣàlàmọnlèkún tó sẹyin gúrúkan
Owó wá kú ọ̀kẹ́ nílé Ọlọfamọjọ
Wọn tún ń pín owow
Wọn ń pín owó
Wọn mú ẹgbàáta
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn sì tún mú ẹgbàáta
Wọn fún Baba Ṣàlàmọnlèkún tó sẹyin gúrúkan
Wọn pín owó náà títì
Owó wá sẹku k’èejì lọ́wọ́ wọn
Wọn sì tún wi
Pé “owó yii, àáti ṣe pin
“T’owó yìí àá fi dija?”
Wọn ní wọn ò yàrá mú nínú owó yìí
Kii wọn ò lọ rèé ra àtàare
Ní wọn ba ra àtàare
Igba ti wọn là àtàare pẹẹ
Ọkọ mẹ́ta ni wọn ba nínú rẹ
Wọn mú ọkọ kìnnì
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn mú ọkọ kejì
Wọn fún Baba Àgùrukansalẹ
Wọn mú ọkọ kẹta
Wọn fún Wọn fún Baba Ṣàlàmọnlèkún tó sẹyin gúrúkan
Bẹẹni wọn parí ìjà ọ̀un nílé Òunmọkà, ọmọ Ayéèjìn

*******************************************

Ọmọ Onmọka, ọmọ Ayéèjìn
Imọka ni ọ, Imọka lémi
Igi gbadagi tí í yọ olóko lẹ́nu
Ọna dóríta mẹ́ta má yà sí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta
Iya Ọlọfa lóku
Baba wọn ló k’ogun Ọlọfa kalẹ
Wọn dikin
Wọn ní ń wá mú tèmi nínú rẹ
Wọn ń wọn ń jogún ilé
Mo lémi ó jẹ
Wọn ní kín jogún aṣọ,
Mo lémi ó jẹ
Ogun dìgòó
Òun lémi ó máa jẹ
Mo wá sáré
Mo lọ rèé mú Abata
Mo délé
Iya na mi jọjọ
Wọn ńi ń lọ rèé tẹ’lu do
Mo ní, n tí máa jẹ?
Wọn ní ń má jẹ ara Ilabata
Ọlalọmi
Ẹni ọba sun
Tó jìnnà kòòròko
Egunmọka
Má gbọ Egun fọ wọyọwọyọ
B’Egun gbélé
Kínní ńṣe tí ó gbọ́dọ̀ pé Yanrìn lookọ?
Pẹ̀lẹ́, ọmọ elewuro Agbamu
Ọmọ óniyanrìn Òndó
Ilabata
Ọmọ tèṣù
Aláta
Ọdún tí wọn tẹ Ọ̀ffàmọka
Ní wọn t’Ayéèjìn
Ọdún kẹtàdínlógún
A tẹ Mọtèṣù
Ẹni Aláta
Eree orí òkìtì
Jingbinni loso
A p’obìnrin Ọ̀ffà Mọka
Wọn t’erèé òun l’egbèje
Òwó mẹ́rìndínlógún
Ní wọn fi owó ère náà se
Ọlalọmi, ọmọ Ayéèjìn
Ọmọ aròunsọlé, ọ̀pá ó dà agogo
Àgbèjàlejù, ara Ọ̀ffà mọjọ
Bẹ́ẹ̀ bá lè yọ niju ọdẹ
Àṣàreta
Kii yọ ọbọ lẹ́nu
Ìjàkadì ó gbọ́dọ̀ hùn ọmọ Ọ̀ffà
Abi ọ nílé Ọlọfa arìntolu
Wọn ju ọ sókè lẹmẹ́ta
Ó dúró tepọn lórí ọpọn wọn
Wọn ní ìwọ Ìyẹ̀ru àríjásòro
Òkun lẹlẹlẹlẹ bí ọwọ́ aṣọ
Àgbèjàlejù, ọmọ Ayéèjìn
Bí ń bá ń lọ lọ́nà ibẹhun
Gbogbo ẹ ló l’àpẹẹrẹ
Ọmọ butubutu kan ìyànni-ìyànni
Ọmọ butubutu kan íyánni-íyánni
Ọmọ butubutu kan ọ̀nà Ọ̀ffà
Kò k’ọmọ n’ìrìn àjò
Ọlalọmi
Wọn ò k’ọmọ ni yíyàn
Ẹni tó dúró
T’o lòun ó là l’Ọ̀ffà
Mo mọ isẹ ti í se
Ẹni tó bẹ̀rẹ̀
T’o lòun ó là l’Ọ̀ffà
Mo mọ isẹ ti í se
Ẹni tó jókòó
T’o lòun ó là l’Ọ̀ffà
Mo mọ isẹ ti í se
Ẹni tó dúró l’Ọ̀ffà, àtà níí rè
Ẹni tó bẹ̀rẹ̀
T’o lòun ó là l’Ọ̀ffà
Oko níí ro
Ẹni tó jókòó
T’o lòun ó là l’Ọ̀ffà
Aṣọ níí hun
Ìyẹ̀ru, abẹ Àkà ó gbà ọmọ ẹṣin
Báluwẹ gbọọrọ ó gbà ọkọ
Ìdídiju láà di l’Ọ̀ffà
Ìdídiju láà di n’Ìyẹ̀ru Ilé
Onmọka, taani ó ní bùn ọ láṣọ?
Igi gbadagi tí yọ olóko lẹ́nu
Mo s’Ọ̀ffà s’Ọ̀ffà nígbàtí ó tó, mo bá wọn tún Ido Ọsun ṣe létí Ẹdẹ
Àgbèjàleri, ara Ọ̀ffà mọjọ
Ọmọ aròunkọlé
Onmọka, ẹni Ayéèjìn
Abojúagada bí iná
Baba iya mi ni
Ó fẹsẹ méjèèjì
Ṣojú omi rukuruku
Baba ẹru bá mi
Agbagun lójú
Baba Asipa
Onilẹ l’àbúrò
Ìrìn gbẹrẹ mo rìn lókè Ogun
Mo b’eléèégun yọ l’Ọ̀yọ́
Mo bá Akìrún ṣe Irẹlẹ
Mo h’ẹla Ilẹkẹ
Níjọ́ Olóyè ń bọ̀ Ogun
Owó mi ni n mo hé
Níjọ́ Ọlalọmi ń sì Ọya
Ọpápá
Mo pá iyùn de Ààfin
Òwuwù
Mo wuyi lọgba Ọ̀ffà
Ọdundun
Níjọ́ Ọlọfa ń ṣe ọsọ Ilé
Àlùkòso Ọlọfa egbèje ni
Aludúndú Ọlọfa
Ẹ̀gbẹ́fa
Kín-in-rìn-jin-gbin-din Ọlọfa
Ẹ̀gbẹ́rìndínlógún
Kí ló ṣe?
Tin ó gbọ “Yẹdé”
Mo mọ òun tó ṣe
Ti ń ó gbō “Yẹdé”
Ọyẹ gbénu
Ọyẹ pọn s’ẹhin
Tí inú ń sunkún ọmú
Ọlalọmi, ọmọ obìbọ ńlá tí í ṣubú l’aró
Ọyẹ t’Akinni kò ti ń bẹ lọ́nà t’Ọ̀ffà
************************************************************

Nlẹ Alakẹ, ọmọ Ọlọfamọjọ
Ọmọ a jẹ ànámọ́ sú sẹ́yìn ẹsẹ bẹtẹ-bẹtẹ
Nlẹ, ọmọ olóko dúdú ìdí Oro,
Ọmọ a pàtàkì tọrún tebè
Ìyẹru Ọkin, Ọlálọmi
Ọmọ abi ìṣù jòókọ, ànámọ́ dijá l’Ọffà
Ìyẹru, bí ọkàn là mi, Ọba níí kò wọn ní róòro.
Ìjàkadì lóró Ọffà
Ọmọ àgbèsáyé, ọmọ ọlọ́rún gbé
Ọmọ yeeye, ẹyin ni.
Ọmọ Ọlọfa a làwọn..
Ọlọ́mọ ló lỌffà, Ọlọfa lo lọ́mọ
Gbéngbé lèkú lára ìyókù ń ṣàn
Pẹki mo bá ọlọfin dimu, kí alẹ to lè má ṣe ọjọ́mu kànrìn kese,
Má sì má na àwọn àgbààgbà l’Ọffà
Èèyàn ti ń bá bájá tí n bá dá,
A jẹ wípé Ọlọfa kọ lo bími
Ẹyin náà ni Ọlọfa,
Ọmọ adìju láṣu
Ọmọ ónibùdó àkọ́ kájú,
Ti mo bá kọ kájú tán má kọ kà’nu
Máa sì má kan àgbon ìsàlẹ̀ worí-worí
Ọmọ húnnún-húnnún-húnnún, ọmọ bọja rẹ wọn,
Ọlálọmi ni bo pẹ títí, àgàrà a má dá orí inú wọn
Óòrẹ Ọffà a sì má rẹjá wọn
Níjọ tí Ọlọfa nlọ si Ọ̀yọ́ Ilé,
Àlùkòso Ọlọ́fa pé egbèje
Alubẹmbẹ Ọlọfa pé ẹgbẹ́fà
Afọnkàkàkí Ọlọfa pé ẹrìndínlógún
Olúkítíkítí dúró gàǹgàn bí ọ̀pá òrìṣà oko.
Bí ó wọdó, eruku ẹṣin,
Bí ó gùn òkè eruku ẹṣin,
O fi ẹsẹ ẹṣin wọ omi rúkurùku lọ́nà t’Ọffà
Ọmọ oroki ni Ọlọ́fa mon jó,
Alára ni òun gbogbo yẹ
Àgbàwọ ṣòkòtò ó yẹ ọmọ ènìyàn
Ti o ba so wọn lẹsẹ, yi o so wọn lápá
Mo rò ìgbà aṣọ tán mo ní sísán lo san
Olúulu ni mo fi lu aṣọ Ọffà mi pòrò
Egungun Ọffà ó gùn, ó sì gbọnlẹ,
Egungun ẹrú dára, ó ju t’ọmọ lọ
Ìjàkadì lóró t’Ọffà
Ọffà ó máka,
Òní bí akà bá lè wò kò wo.
Ẹni tí ó ní jẹ ìyàn ànámọ́, olúwa rẹ o ni de Ọffà ni
Ẹ má mú mi lỌffà, ẹ wo mi lójú náa
Ọmọ abi ìṣù jòókọ….

*Fully Compiled by Jimson Jaat Taofik, alias Pen Priest. A Student of Ancient and Modern Histories, Trained Journalist, Author, Blogger, Litterateur, Printrovert, Editor and Bibliophile.*

*CONTACTS*
*Facebook: Jimoh Taofik Adekunle*
Twitter: @jimsonjaat01
Gmail: deskofinsanity96@gmail.com
Phone: 08144510532

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *